Native Bible

Genesis 30:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀nà mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó.”

Genesis 30:26 in English

Genesis 30:26 · Berean Standard Bible

Give me my wives and children for whom I have served you, that I may go on my way. You know how hard I have worked for you.”

Context

24Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Josẹfu, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún un fún mi.” 25Lẹ́yìn tí Rakeli ti bí Josẹfu, Jakọbu wí fún Labani pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá. 26Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀nà mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó.” 27Ṣùgbọ́n Labani wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ. 28Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.