Native Bible

Genesis 3:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

Genesis 3:21 in English

Genesis 3:21 · Berean Standard Bible

And the LORD God made garments of skin for Adam and his wife, and He clothed them.

Context

19Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.” 20Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè. 21Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. 22Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.” 23Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.