Gẹnẹsisi 3:14
Genesis 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
Genesis 3:14 in English
Genesis 3:14 · Berean Standard Bible
So the LORD God said to the serpent: “Because you have done this, cursed are you above all livestock and every beast of the field! On your belly will you go, and dust you will eat, all the days of your life.
Context
12Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” 13Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”
Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” 14Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,
“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn
àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!
Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,
ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 15Èmi yóò sì fi ọ̀tá
sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,
àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;
òun yóò fọ́ orí rẹ,
ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.” 16Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé,
“Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;
ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.
Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,
òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.