Native Bible

Genesis 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

Genesis 3:13 in English

Genesis 3:13 · Berean Standard Bible

Then the LORD God said to the woman, “What is this you have done?” “The serpent deceived me,” she replied, “and I ate.”

Context

11Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?” 12Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” 13Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.” 14Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 15Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.