Native Bible

Genesis 27:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”

Genesis 27:32 in English

Genesis 27:32 · Berean Standard Bible

But his father Isaac replied, “Who are you?” “I am Esau, your firstborn son,” he answered.

Context

30Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. 31Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.” 32Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.” 33Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!” 34Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.