Gẹnẹsisi 27:30
Genesis 27:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé.
Genesis 27:30 in English
Genesis 27:30 · Berean Standard Bible
As soon as Isaac had finished blessing him and Jacob had left his father’s presence, his brother Esau returned from the hunt.
Context
28Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run
àti nínú ọ̀rá ilẹ̀
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun. 29Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́,
kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ,
máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ,
kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ
Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú,
ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.” 30Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. 31Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.” 32Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?”
Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.