Native Bible

Genesis 27:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Isaaki baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnukò mí ní ẹnu.”

Genesis 27:26 in English

Genesis 27:26 · Berean Standard Bible

Then his father Isaac said to him, “Please come near and kiss me, my son.”

Context

24ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.” 25Nígbà náà ni Isaaki wí pé, “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.” Jakọbu sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú. 26Nígbà náà ni Isaaki baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnukò mí ní ẹnu.” 27Ó sì súnmọ́ ọn, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà tí Isaaki gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún un ó wí pé, “Wò ó òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí Olúwa ti bùkún. 28Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.