Gẹnẹsisi 26:23
Genesis 26:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba.
Genesis 26:23 in English
Genesis 26:23 · Berean Standard Bible
From there Isaac went up to Beersheba,
Context
21Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna. * 22Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, Olúwa ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.” 23Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba. 24Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ. Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.” 25Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.