Gẹnẹsisi 26:25
Genesis 26:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.
Genesis 26:25 in English
Genesis 26:25 · Berean Standard Bible
So Isaac built an altar there and called on the name of the LORD, and he pitched his tent there. His servants also dug a well there.
Context
23Láti ibẹ̀, ó kúrò lọ sí Beerṣeba. 24Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, Olúwa sì fi ara hàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu baba rẹ. Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùsi fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Abrahamu ìránṣẹ́ mi.” 25Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ Olúwa. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀. 26Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. 27Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.