Native Bible

Genesis 25:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo.

Genesis 25:18 in English

Genesis 25:18 · Berean Standard Bible

Ishmael’s descendants settled from Havilah to Shur, which is near the border of Egypt as you go toward Asshur.* And they lived in hostility toward all their brothers.

Context

16Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn. 17Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. 18Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo. 19Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu. Abrahamu bí Isaaki. 20Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.