Gẹnẹsisi 25:17
Genesis 25:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
Genesis 25:17 in English
Genesis 25:17 · Berean Standard Bible
Ishmael lived a total of 137 years. Then he breathed his last and died, and was gathered to his people.
Context
15Hadadi, Tema, Jeturi,
Nafiṣi, àti Kedema. 16Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn. 17Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. 18Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo. 19Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu.
Abrahamu bí Isaaki.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.