Gẹnẹsisi 24:6
Genesis 24:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”
Genesis 24:6 in English
Genesis 24:6 · Berean Standard Bible
Abraham replied, “Make sure that you do not take my son back there.
Context
4Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” 5Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?” 6Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” 7“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. 8Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.