Native Bible

Genesis 24:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì fi kún un pé, “Àwa ní koríko àti ṣakaṣaka tó pẹ̀lú, àti ààyè láti wọ̀ sí.”

Genesis 24:25 in English

Genesis 24:25 · Berean Standard Bible

Then she added, “We have plenty of straw and feed, as well as a place for you to spend the night.”

Context

23Lẹ́yìn náà, ó béèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ í ṣe? Jọ̀wọ́ wí fún mi, ǹjẹ́ ààyè wà ní ilé baba rẹ láti wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?” 24Ó dáhùn pé, “Betueli ọmọ tí Milka bí fún Nahori ni baba mi.” 25Ó sì fi kún un pé, “Àwa ní koríko àti ṣakaṣaka tó pẹ̀lú, àti ààyè láti wọ̀ sí.” 26Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa, 27wí pe, “Olùbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi ti kò jẹ́ kí àánú àti òtítọ́ rẹ̀ kí ó yẹ̀ lọ́dọ̀ olúwa mi. Ní ti èmi Olúwa ti darí ìrìnàjò mi sí ilé ìbátan olúwa mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.