Gẹnẹsisi 23:4
Genesis 23:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”
Genesis 23:4 in English
Genesis 23:4 · Berean Standard Bible
“I am a foreigner and an outsider among you. Give me a burial site among you so that I can bury my dead.”
Context
2Ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara. 3Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé, 4“Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.” 5Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé, 6“Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.