Native Bible

Genesis 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí,

Genesis 22:16 in English

Genesis 22:16 · Berean Standard Bible

saying, “By Myself I have sworn, declares the LORD, that because you have done this and have not withheld your only son,

Context

14Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Jehofah Jire.* Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.” 15Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. 16Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, 17nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, 18àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.