Gẹnẹsisi 22:17
Genesis 22:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn,
Genesis 22:17 in English
Genesis 22:17 · Berean Standard Bible
I will surely bless you, and I will multiply your descendants * like the stars in the sky and the sand on the seashore. Your descendants will possess the gates of their enemies.
Context
15Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. 16Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, 17nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, 18àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.” 19Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.