Native Bible

Genesis 21:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe.

Genesis 21:22 in English

Genesis 21:22 · Berean Standard Bible

At that time Abimelech and Phicol the commander of his army said to Abraham, “God is with you in all that you do.

Context

20Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà. 21Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá. 22Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. 23Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.” 24Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.