Gẹnẹsisi 18:26
Genesis 18:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
Genesis 18:26 in English
Genesis 18:26 · Berean Standard Bible
So the LORD replied, “If I find fifty righteous ones within the city of Sodom, on their account I will spare the whole place.”
Context
24“Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? 25Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?” 26Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.” 27Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, 28bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?”
Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.