Native Bible

Genesis 18:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”

Genesis 18:28 in English

Genesis 18:28 · Berean Standard Bible

suppose the fifty righteous ones lack five. Will You destroy the whole city for the lack of five?” He replied, “If I find forty-five there, I will not destroy it.”

Context

26Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.” 27Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, 28bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.” 29Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.” 30Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.