Gẹnẹsisi 18:24
Genesis 18:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?
Genesis 18:24 in English
Genesis 18:24 · Berean Standard Bible
What if there are fifty righteous ones in the city? Will You really sweep it away and not spare the place for the sake of the fifty righteous ones who are there?
Context
22Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa. 23Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” 24“Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? 25Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?” 26Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.