Gẹnẹsisi 18:11
Genesis 18:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó, Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ.
Genesis 18:11 in English
Genesis 18:11 · Berean Standard Bible
And Abraham and Sarah were already old and well along in years; Sarah had passed the age of childbearing.
Context
9Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ń kọ́?”
Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” 10Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”
Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. 11Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó, Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. 12Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?” 13Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.