Native Bible

Genesis 18:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà.

Genesis 18:10 in English

Genesis 18:10 · Berean Standard Bible

Then the LORD said, “I will surely return to you at this time next year, and your wife Sarah will have a son!” Now Sarah was behind him, listening at the entrance to the tent.

Context

8Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé síwájú wọn. Ó sì dúró nítòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́. 9Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ń kọ́?” Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” 10Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. 11Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó, Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. 12Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.