Gẹnẹsisi 16:14
Genesis 16:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi; kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi.
Genesis 16:14 in English
Genesis 16:14 · Berean Standard Bible
Therefore the well was called Beer-lahai-roi.* It is located between Kadesh and Bered.
Context
12Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn
ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,
ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,
yóò sì máa gbé ní ìkanra
pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.” 13Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” 14Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi; kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi. 15Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. 16Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.