Gẹnẹsisi 16:11
Genesis 16:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé, “Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli, nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
Genesis 16:11 in English
Genesis 16:11 · Berean Standard Bible
The angel of the LORD proceeded: “Behold, you have conceived and will bear a son. And you shall name him Ishmael,* for the LORD has heard your cry of affliction.
Context
9Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” 10Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.” 11Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé,
“Ìwọ ti lóyún,
ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.
Ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli,
nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ. 12Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn
ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,
ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,
yóò sì máa gbé ní ìkanra
pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.” 13Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.