Gẹnẹsisi 14:6
Genesis 14:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù.
Genesis 14:6 in English
Genesis 14:6 · Berean Standard Bible
and the Horites in the area of Mount Seir, as far as El-paran, which is near the desert.
Context
4Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i. 5Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, 6àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù. 7Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (ti o túmọ̀ sí Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú. 8Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.