Native Bible

Genesis 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.

Genesis 14:4 in English

Genesis 14:4 · Berean Standard Bible

For twelve years they had been subject to Chedorlaomer, but in the thirteenth year they rebelled.

Context

2jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari) jagun. 3Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Siddimu (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀). 4Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i. 5Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, 6àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.