Gẹnẹsisi 11:1
Genesis 11:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.
Genesis 11:1 in English
Genesis 11:1 · Berean Standard Bible
Now the whole world had one language and a common form of speech.
Context
1Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. 2Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari,* wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. 3Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.