Galatia 3:5
Galatians 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́?
Galatians 3:5 in English
Galatians 3:5 · Berean Standard Bible
Does God lavish His Spirit on you and work miracles among you because you practice the law, or because you hear and believe?
Context
3Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? 4Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. 5Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? 6Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.” 7Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.