Native Bible

Ezra 8:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jerusalẹmu, níbi tí a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.

Ezra 8:32 in English

Ezra 8:32 · Berean Standard Bible

So we arrived at Jerusalem and rested there for three days.

Context

30Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ tí a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerusalẹmu. 31Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Ahafa láti lọ sí Jerusalẹmu. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa. 32Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jerusalẹmu, níbi tí a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta. 33Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 34Gbogbo nǹkan ni a kà, tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ní ìgbà náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.