Native Bible

Ezra 8:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

Ezra 8:33 in English

Ezra 8:33 · Berean Standard Bible

On the fourth day, in the house of our God, we weighed out the silver and gold and sacred articles into the hand of Meremoth son of Uriah, the priest. Eleazar son of Phinehas was with him, along with the Levites Jozabad son of Jeshua and Noadiah son of Binnui.

Context

31Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Ahafa láti lọ sí Jerusalẹmu. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa. 32Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jerusalẹmu, níbi tí a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta. 33Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Meremoti ọmọ Uriah lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Eleasari ọmọ Finehasi wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi; Josabadi ọmọ Jeṣua àti Noadiah ọmọ Binnui wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 34Gbogbo nǹkan ni a kà, tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ní ìgbà náà. 35Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí ó ti padà láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ sísun sí Ọlọ́run Israẹli: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Israẹli, àgbò mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún, ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, àti òbúkọ méjìlá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo èyí jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.