Esra 7:15
Ezra 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu,
Ezra 7:15 in English
Ezra 7:15 · Berean Standard Bible
Moreover, you are to take with you the silver and gold that the king and his counselors have freely offered to the God of Israel, whose dwelling is in Jerusalem,
Context
13Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. 14Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu. 15Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, 16pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu. 17Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.