Esra 7:14
Ezra 7:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu.
Ezra 7:14 in English
Ezra 7:14 · Berean Standard Bible
You are sent by the king and his seven counselors to evaluate Judah and Jerusalem according to the Law of your God, which is in your hand.
Context
12Artasasta, ọba àwọn ọba.
Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run.
Àlàáfíà. 13Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. 14Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu. 15Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, 16pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.