Native Bible

Ezra 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Artasasta, ọba àwọn ọba. Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run. Àlàáfíà.

Ezra 7:12 in English

Ezra 7:12 · Berean Standard Bible

Artaxerxes, king of kings. To Ezra the priest, the scribe of the Law of the God of heaven: Greetings.*

Context

10Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli. 11Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà ti ọba Artasasta fún àlùfáà Esra olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Israẹli. 12Artasasta, ọba àwọn ọba. Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run. Àlàáfíà. 13Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. 14Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.