Esra 6:17
Ezra 6:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Ezra 6:17 in English
Ezra 6:17 · Berean Standard Bible
For the dedication of the house of God they offered a hundred bulls, two hundred rams, four hundred lambs, and a sin offering for all Israel of twelve male goats, one for each tribe of Israel.
Context
15A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi. 16Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. 18Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose. 19Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nisani,* àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.