Native Bible

Ezra 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.

Ezra 6:15 in English

Ezra 6:15 · Berean Standard Bible

And this temple was completed on the third day of the month of Adar,* in the sixth year of the reign of King Darius.

Context

13Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dariusi pa, Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate, àti Ṣetar-bosnai pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pa á mọ́ láìyí ọ̀kan padà. 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀. 15A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi. 16Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.