Esra 6:18
Ezra 6:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.
Ezra 6:18 in English
Ezra 6:18 · Berean Standard Bible
They also appointed the priests by their divisions and the Levites by their groups to the service of God in Jerusalem, according to what is written in the Book of Moses.
Context
16Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀. 17Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli. 18Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose. 19Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nisani,* àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá. 20Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.