Esra 6:1
Ezra 6:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli.
Ezra 6:1 in English
Ezra 6:1 · Berean Standard Bible
Thus King Darius ordered a search of the archives stored in the treasury of Babylon.
Context
1Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli. 2A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀.
Ìwé ìrántí. 3Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.
Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.