Esra 6:2
Ezra 6:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí.
Ezra 6:2 in English
Ezra 6:2 · Berean Standard Bible
And a scroll was found in the fortress of Ecbatana, in the province of Media, with the following written on it: Memorandum:
Context
1Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli. 2A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀.
Ìwé ìrántí. 3Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu.
Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà, 4pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.