Esra 10:19
Ezra 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀.
Ezra 10:19 in English
Ezra 10:19 · Berean Standard Bible
They pledged to send their wives away, and for their guilt they presented a ram from the flock as a guilt offering.
Context
17ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. 18Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.
Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ:
Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah. 19Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀. 20Nínú ìran Immeri:
Hanani àti Sebadiah. 21Nínú ìran Harimu:
Maaseiah, Elijah, Ṣemaiah, Jehieli àti Ussiah.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.