Esra 10:12
Ezra 10:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé, ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí.
Ezra 10:12 in English
Ezra 10:12 · Berean Standard Bible
And the whole assembly responded in a loud voice: “Truly we must do as you say!
Context
10Nígbà náà ni àlùfáà Esra dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìṣòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Israẹli. 11Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.” 12Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé, ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí. 13Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí síbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró ní ìta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrín ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí. 14Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ́ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.