Esra 10:11
Ezra 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.”
Ezra 10:11 in English
Ezra 10:11 · Berean Standard Bible
Now, therefore, make a confession to the LORD, the God of your fathers, and do His will. Separate yourselves from the people of the land and from your foreign wives.”
Context
9Láàrín ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Juda àti Benjamini tí péjọ sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsànán, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ràn yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀. 10Nígbà náà ni àlùfáà Esra dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìṣòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Israẹli. 11Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.” 12Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé, ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí. 13Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí síbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró ní ìta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrín ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.