Esekiẹli 7:5
Ezekiel 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo. Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!
Ezekiel 7:5 in English
Ezekiel 7:5 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says: ‘Disaster! An unprecedented disaster *— behold, it is coming!
Context
3Òpin tí dé sí ọ báyìí,
èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ,
èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ,
èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ. 4Ojú mi kò ní i dá ọ sì,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú;
ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ.
Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ 5“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo.
Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ! 6Òpin ti dé!
Òpin ti dé!
Ó ti dìde lòdì sí ọ.
Kíyèsi, ó ti dé! 7Ìparun ti dé sórí rẹ,
ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà.
Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé!
Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.