Esekiẹli 7:2
Ezekiel 7:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli: “ ‘Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!
Ezekiel 7:2 in English
Ezekiel 7:2 · Berean Standard Bible
“O son of man, this is what the Lord GOD says to the land of Israel: ‘The end! The end has come upon the four corners of the land.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli:
“ ‘Òpin! Òpin ti dé
sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà! 3Òpin tí dé sí ọ báyìí,
èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ,
èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ,
èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ. 4Ojú mi kò ní i dá ọ sì,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú;
ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ.
Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.