Native Bible

Ezekiel 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.

Ezekiel 5:3 in English

Ezekiel 5:3 · Berean Standard Bible

But you are to take a few strands of hair and secure them in the folds of your garment.

Context

1“Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in. 2Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká. 3Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ. 4Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli. 5“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn Orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.