Esekiẹli 48:6
Ezekiel 48:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn.
Ezekiel 48:6 in English
Ezekiel 48:6 · Berean Standard Bible
Reuben will have one portion bordering the territory of Ephraim from east to west.
Context
4Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn. 5Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 6Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn. 7Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 8“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.