Native Bible

Ezekiel 48:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

Ezekiel 48:7 in English

Ezekiel 48:7 · Berean Standard Bible

Judah will have one portion bordering the territory of Reuben from east to west.

Context

5Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 6Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn. 7Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn. 8“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀. 9“Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.