Esekiẹli 44:5
Ezekiel 44:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.
Ezekiel 44:5 in English
Ezekiel 44:5 · Berean Standard Bible
The LORD said to me: “Son of man, pay attention; look carefully with your eyes and listen closely with your ears to everything I tell you concerning all the statutes and laws of the house of the LORD. Take careful note of the entrance to the temple, along with all the exits of the sanctuary.
Context
3Ọmọ-aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.” 4Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀. 5Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́. 6Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Israẹli! 7Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjèjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkulò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.