Native Bible

Ezekiel 44:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ-aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”

Ezekiel 44:3 in English

Ezekiel 44:3 · Berean Standard Bible

Only the prince himself may sit inside the gateway to eat in the presence of the LORD. He must enter by way of the portico of the gateway and go out the same way.”

Context

1Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wà ní títì. 2Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu-ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí gbà ibẹ̀ wọlé. 3Ọmọ-aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.” 4Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀. 5Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáradára, fetísílẹ̀ dáradára kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa òfin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu-ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.