Esekiẹli 44:2
Ezekiel 44:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu-ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí gbà ibẹ̀ wọlé.
Ezekiel 44:2 in English
Ezekiel 44:2 · Berean Standard Bible
And the LORD said to me, “This gate is to remain shut. It shall not be opened, and no man shall enter through it, because the LORD, the God of Israel, has entered through it. Therefore it will remain shut.
Context
1Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí ibi mímọ́, èyí tí ó kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wà ní títì. 2Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu-ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tí gbà ibẹ̀ wọlé. 3Ọmọ-aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu-ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìloro ẹnu-ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.” 4Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu-ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.