Esekiẹli 43:4
Ezekiel 43:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá.
Ezekiel 43:4 in English
Ezekiel 43:4 · Berean Standard Bible
and the glory of the LORD entered the temple through the gate facing east.
Context
2mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀. 3Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀. 4Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá. 5Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run. 6Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.